X hits on this document

64 views

0 shares

0 downloads

0 comments

3 / 5

aba wo awon ikan ti ijo yi gbe dani:- Alakoko, won ni eni akoko je iran alawodudu; ara Asia ni, ohun lo da gbogbo ikan, oun loni aiye ohun baba olaju, olorun gbogbo agbaye.

_   Elekeji Alawodudu gan ni olorun ti oruko re nje Allah, “owo ese ori”.

Gbolohun mejeji yi tako oro Islam, ti o so pe Allah, Olohun ni, Aseda gbogbo ikan. Ninu Alukuraani Olohun Oba sope ohun lo da enia ati gbogbo ikan pata. Nitorina, ko ba oju mu fun enia kan lati pe ara re ni Olohun. Ekeji igbagbo ijo yi fihan wipe aroso ati adada sile ni awon oro na. Eyiti awon ijo yi gbe dani ko ni nkanse pelu Islam.  Oga won ti won pe oruko re Yacob, ati enikan ti won pe ni anobi ti oruko re nje W. D. Fard, a ti igbagbo won sori pe awon eniya alawodudu ni o daraju.  Sugbon Anabi wa Muhammed (SAW) ti benu ete lu iru oro bayi nipa eleya meya ni oro ikehin ti o so ko to jade laiye ni pa gbolohun yi:-

“Eyin enia mi, Olohun yin, eyo kan soso ni, ati pe baba yin, okan ni (Adam).  Gbogbo yin wa lati ebi kan soso ti se Adam.  Beni ada Adam lati inu amo kosi ajulo fun omo Arab lori eniti ki se Arab, bakanna, eniti ki ise Arab koju Arab lo. Beni Alawo funfun Ko daraju alawo dudu lo ati pe Alawo dudu ko dara ju alawo funfun lo ayafi ninu iwa mimo ati rere.  Nitorina Eni ti odara ju lo ni eniti opaya Olohun”.  Fun eniti oba fe mo asiri awon ijo mejeji yi, kio lo ka iwe itan igbesi aiye ogbeni ologbe Malik Al- Shabax (Malcom X).

Ijo Ahmadiyya/Qadiani

Ijo Ahmadiyya ti won dide nilu orilede India labe atilehin ijoba British lo fi igbagbo won ha gege bi eniti benu ete si Islam.  Ninu opolopo igbagbo won ni wipe Anabi Mohammed (S.A.W) kise Anobi Ikehin eleyi tio je Okan ninu nkan ti musulumi ni lati gbagbo bakanna ni Quran ati hadith tenu mo oro na ati apapo awon ajogbon ninu Islam.  

Quran sura 33 ayat 40 sope:-Eyin enia, Muhammed (S.A.W) koni omo kunrin larin yin, sugbon ohun ni ojise Olohun, ohun si ni igbehin ninu awon Anobi. Atipe Olohun mo ohun gbogbo”.  Anabi wa Alaponle Muhammed (S.A.W) sowi pe: Awon Anobi ni ose itosona fun awon omo Israeli.  Ti Anabi kan ba papoda, Anobi miran ni yio ropo re sugbon Anobi kan ko ni wa mo lehin mi.

Awon Ahmadiyya je omoleyin enikan ti anpe ni Mirza Ghulam Ahmad omo Qadiani ti oni Anabi ni ohun. O si tokasi awon hadith kan tiko fese mule lati fi yi opolopo oro Alukurani lati fi gbe rare lese sugbon sa, Anabi Muhammad fun rare ti se ikilo:- “Oni asiko kan nbo ti awon opuro bi ogbon (30) (dajjals) eyiti olukaluku yio pe ara won ni Anabi lati odo Olohun (Sahih Bukhari, ati Sahih Muslim).  Leyin igba die ti Anabi Muhammad (S.A.W) ku, okunrin kan toje Musailama, lo pe ara re ni anobi. Won si gbe ogun ti pelu awon omo lehin re fun oro iskuso.  O je ohun iya lenu lati ri pe ogbeni Musailama ko tako Anabi Muhammad (S.A.W) ati awon omolehin Anabi. O tun je ikan iyalenu pe, iru oro bayi lo tan ara ilu Banu Hunaifa lati gba fun Musailama to

Document info
Document views64
Page views64
Page last viewedFri Dec 16 09:10:24 UTC 2016
Pages5
Paragraphs45
Words2335

Comments