X hits on this document

67 views

0 shares

0 downloads

0 comments

4 / 5

pe ara re ni anobi.  

Sibesibe, eyi to je apapo ajoro awon saabe (Companions) ni pe isokuso ni ogbeni na so ati wipe won ijo Ahmadiyya ni keferi fun agboye oroyi, eje kalo ka akosile yii:-

“Apere miran to han pe Ahmadiyya ko gba Alukurani ati sunna gbo nipe won ni Jesu ti ku, ati pe Mirza Ghulam Ahmad ni Jesu ti o pa da wa si aiye.  Ti a ba tun wo oro to wa ninu Encyclopadia Britanica 1985, Mirza Ghulam Ahmad so pe ki se wipe ohun ni Jesu ni kan, ohun kanna ni Anabi Muhammad, ohun kanna ni Mahammad, ohun kanna ni mahdi, atipe ohun kanna ni Krishna ti se olorun Hindu. Eyi ni la ti mu wa pada si ki esin Islam duro le lori gegebi ije okan Olohun. Bi enikan ba so pe olorun ni ohun, to tun je olorun Hindu, iru eni be ti koja aye re gegebi oro Alukuran. Islam  ko fi aye gba iru oro bayi.  Ni akotan, Ijo Ahmadiyya ko fara mo Jihad lati le tako agbekale ti Musulumi ko fi fe ijoba amunisin British.

The International Community of Submitters

Awon Ijo olujuraeni sile ti o je omoleyin ologbe Rashid Khalifa, okunrin kan to pe ara re ni ojise Olohun. Awon oro ti o dimu to ohun ti won ni lati yo kuro ninu ijo Islam. Nitori Oro Alukurani sura 33 aya 40 pe: “Eyin enia, Muhammad koni omokunrin larin yin sugbon ohun ni Anobi, Ojise Olohun ohun si ni Igbehin ati opin awon Anabi. Olohun si mo ohun gbogbo.

Anabi Muhammed (S.A.W) ti se ikilo fun Musulumi ki won ma se jin sinu ofin iru awon ijo bayi. Abu Rafi logba Hadith na wa to so wipe Anabi ni “Ma se je ki ri ikan ninu yi ki o ma fi idi rin le ninu ikan ti mo pa lase tabi lewo fun yin (ninu Sunnah Anabi Muhammad ) o si so bayi pe, gbogbo ikan ti a ri ninu iwe Olohun ni a ni lati tele ( Book 40, Number 4558 of Sunnah Abu Dawud).

Bakanna ni Anabi Muhammad (S.W.A) sope iran omo Israeli, awon Anabi ni ojise won.  “Nigba ti anobi kan ba papoda, Anobi miran o ma ropo sugbon lehin mi kosi Anobi miran mo ayafi khalifa ni yi o ma ropo mi” (Sahih Bukhari).

Opolopo isina ti ogben Rashid khalifa mu ba awon eniyan ni a ri nitori pe onfe agbara to fe ma lo.  Irufe nkan bayi ti mu opolopo enia sina lati gba pipe.  Ogbeni Khalifa sope Alukurani kun fun asiri ti oromo mokandinlogun (19). Eleyi je ki won yo ayatmeji kuro ninu Alukurani ki o ba le ma lo fun ikan miran yato si Islam,  ayat kansoso kuro ninu alukurani ti je ki ijo yi lodi si Alukuriani sura 2 aya 85 to so wipe:-Se iwo gba apa kan kurani gbo ti o si tako a pa kan bi ? kini idajo iru eni be  bi kise abuku ile aiye ati ti Alikiyaoma nibiti a o ti ju won si nu iya to tobi ju lo.

Document info
Document views67
Page views67
Page last viewedMon Jan 23 23:25:49 UTC 2017
Pages5
Paragraphs45
Words2335

Comments